1 Ọba 5:3
1 Kings 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
1 Kings 5:3 in English
1 Kings 5:3 · Berean Standard Bible
“As you are well aware, due to the wars waged on all sides against my father David, he could not build a house for the Name of the LORD his God until the LORD had put his enemies under his feet.
Context
1Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. 2Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé, 3“Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe. 5Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.