Native Bible

1 Kings 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi.

1 Kings 3:7 in English

1 Kings 3:7 · Berean Standard Bible

And now, O LORD my God, You have made Your servant king in my father David’s place. But I am only a little child, not knowing how to go out or come in.

Context

5Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.” 6Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́. 7“Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.