Native Bible

1 Kings 3:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!”

1 Kings 3:26 in English

1 Kings 3:26 · Berean Standard Bible

Then the woman whose son was alive spoke to the king because she yearned with compassion for her son. “Please, my lord,” she said, “give her the living baby. Do not kill him!” But the other woman said, “He will be neither mine nor yours. Cut him in two!”

Context

24Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba. 25Ọba sì pàṣẹ pé, “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.” 26Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!” Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!” 27Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.” 28Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.