1 Ọba 3:1
1 Kings 3:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká.
1 Kings 3:1 in English
1 Kings 3:1 · Berean Standard Bible
Later, Solomon formed an alliance with Pharaoh king of Egypt by marrying his daughter. Solomon brought her to the City of David until he had finished building his palace and the house of the LORD, as well as the wall around Jerusalem.
Context
1Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká. 2Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tí ì kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa títí di ìgbà náà 3Solomoni sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.