Native Bible

1 Kings 20:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.

1 Kings 20:33 in English

1 Kings 20:33 · Berean Standard Bible

Now the men were looking for a sign of hope, and they quickly grasped at this word and replied, “Yes, your brother Ben-hadad.” “Go and get him!” said the king. Then Ben-hadad came out, and Ahab had him come up into his chariot.

Context

31Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.” 32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.” 33Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́. 34Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.” Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ. 35Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.