1 Ọba 20:30
1 Kings 20:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá mẹ́tàlá lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.
1 Kings 20:30 in English
1 Kings 20:30 · Berean Standard Bible
The rest of them fled into the city of Aphek, where the wall fell on twenty-seven thousand of the remaining men. Ben-hadad also fled to the city and hid in an inner room.
Context
28Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ” 29Wọ́n sì dó sí òdìkejì ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Israẹli sì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn ará Aramu ní ọjọ́ kan. 30Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Afeki, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàá mẹ́tàlá lé ẹgbẹ̀rún (27,000) nínú wọn. Beni-Hadadi sì sálọ sínú ìlú, ó sì fi ara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù. 31Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.” 32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ”
Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.