1 Ọba 20:22
1 Kings 20:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”
1 Kings 20:22 in English
1 Kings 20:22 · Berean Standard Bible
Afterward, the prophet approached the king of Israel and said, “Go and strengthen your position, and take note what you must do, for in the spring * the king of Aram will come up against you.”
Context
20Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Aramu sì sá, Israẹli sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Beni-Hadadi ọba Aramu sì sálà lórí ẹṣin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin. 21Ọba Israẹli sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Aramu ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 22Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Israẹli, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Aramu yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.” 23Àwọn ìránṣẹ́ ọba Aramu sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú. 24Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe, mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi baálẹ̀ sí ipò wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.