Native Bible

1 Kings 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

1 Kings 2:5 in English

1 Kings 2:5 · Berean Standard Bible

Moreover, you know what Joab son of Zeruiah did to me—what he did to Abner son of Ner and Amasa son of Jether,* the two commanders of the armies of Israel. He killed them in peacetime to avenge the blood of war. He stained with the blood of war the belt around his waist and the sandals on his feet.*

Context

3kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, 4kí Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé, ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’ 5“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 6Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà. 7“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.