Native Bible

1 Kings 2:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀.

1 Kings 2:31 in English

1 Kings 2:31 · Berean Standard Bible

And the king replied, “Do just as he says. Strike him down and bury him, and so remove from me and from the house of my father the innocent blood that Joab shed.

Context

29A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.” 30Benaiah sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Joabu pé, “Ọba sọ wí pé, ‘Jáde wá.’ ” Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò kú níhìn-ín.” Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.” 31Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. 32Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ. 33Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.