1 Ọba 19:3
1 Kings 19:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀,
1 Kings 19:3 in English
1 Kings 19:3 · Berean Standard Bible
And Elijah was afraid and ran for his life. When he came to Beersheba in Judah, he left his servant there,
Context
1Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì. 2Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.” 3Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, 4nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ.” 5Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ.
Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.