Native Bible

1 Kings 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá.

1 Kings 19:12 in English

1 Kings 19:12 · Berean Standard Bible

After the earthquake there was a fire, but the LORD was not in the fire. And after the fire came a still, small voice.

Context

10(9) Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?” (10) Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.” 11Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. 12Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. 13Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?” 14Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.