Native Bible

1 Kings 18:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.”

1 Kings 18:41 in English

1 Kings 18:41 · Berean Standard Bible

And Elijah said to Ahab, “Go up, eat and drink, for there is the sound of a heavy rain.”

Context

39Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “Olúwa, òun ni Ọlọ́run! Olúwa, òun ni Ọlọ́run!” 40Nígbà náà ni Elijah sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Baali. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sálọ!” Wọ́n sì mú wọn, Elijah sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí àfonífojì Kiṣoni, ó sì pa wọ́n níbẹ̀. 41Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.” 42Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Elijah gun orí òkè Karmeli lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀. 43Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.