1 Ọba 17:19
1 Kings 17:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀.
1 Kings 17:19 in English
1 Kings 17:19 · Berean Standard Bible
But Elijah said to her, “Give me your son.” So he took him from her arms, carried him to the upper room where he was staying, and laid him on his own bed.
Context
17Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú. 18Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?” 19Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀. 20Nígbà náà ni ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?” 21Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.