1 Ọba 16:18
1 Kings 16:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú,
1 Kings 16:18 in English
1 Kings 16:18 · Berean Standard Bible
When Zimri saw that the city was captured, he entered the citadel of the royal palace and burned it down upon himself. So he died
Context
16Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí ó dó tì gbọ́ wí pé Simri ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Omri, olórí ogun, bí ọba lórí Israẹli ní ọjọ́ náà ní ibùdó. 17Nígbà náà ni Omri àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gibetoni, wọ́n sì dó ti Tirsa. 18Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú, 19nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú Olúwa àti ní rírìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀. 20Ní ti ìyókù ìṣe Simri, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.