1 Ọba 16:11
1 Kings 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Baaṣa pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́.
1 Kings 16:11 in English
1 Kings 16:11 · Berean Standard Bible
As soon as Zimri began to reign and was seated on the throne, he struck down the entire household of Baasha. He did not leave a single male, whether a kinsman or friend.
Context
9Simri, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Ela sì wà ní Tirsa nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Arsa, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tirsa. 10Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 11Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Baaṣa pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́. 12Bẹ́ẹ̀ ni Simri pa gbogbo ilé Baaṣa run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ sí Baaṣa nípa ọwọ́ Jehu wòlíì: 13nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa àti Ela ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Israẹli ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú Olúwa Ọlọ́run Israẹli bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.