Native Bible

1 Kings 13:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ”

1 Kings 13:22 in English

1 Kings 13:22 · Berean Standard Bible

but you went back and ate bread and drank water in the place where He told you not to do so, your body shall never reach the tomb of your fathers.’”

Context

20Bí wọ́n sì ti jókòó ti tábìlì, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ wòlíì tí ó mú un padà wá pé; 21Ó sì kígbe sí ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti Juda wá wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti ba ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́, ìwọ kò sì pa àṣẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́. 22Ìwọ padà, ìwọ sì ti jẹ oúnjẹ, ìwọ sì ti mu omi níbi tí ó ti sọ fún ọ pé kí ìwọ kí ó má ṣe jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Nítorí náà, a kì yóò sin òkú rẹ sínú ibojì àwọn baba rẹ.’ ” 23Nígbà tí ènìyàn Ọlọ́run sì ti jẹun tán àti mu omi tan, wòlíì tí ó ti mú u padà sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún un. 24Bí ó sì ti ń lọ ní ọ̀nà rẹ̀, kìnnìún kan pàdé rẹ̀ ní ọ̀nà, ó sì pa á, a sì gbé òkú rẹ̀ sọ sí ojú ọ̀nà, pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti kìnnìún tí ó dúró tì í lẹ́gbẹ̀ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.