Native Bible

1 Kings 11:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni.

1 Kings 11:7 in English

1 Kings 11:7 · Berean Standard Bible

At that time on a hill east of Jerusalem, Solomon built a high place for Chemosh the abomination of Moab and for Molech the abomination of the Ammonites.

Context

5Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. 6Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. 7Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni. 8Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn. 9Olúwa bínú sí Solomoni nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.