Native Bible

1 Kings 11:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jeroboamu jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Solomoni sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Josẹfu.

1 Kings 11:28 in English

1 Kings 11:28 · Berean Standard Bible

Now Jeroboam was a mighty man of valor. So when Solomon noticed that the young man was industrious, he put him in charge of the whole labor force of the house of Joseph.

Context

26Bákan náà Jeroboamu ọmọ Nebati sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Solomoni, ará Efraimu ti Sereda, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Serua. 27Èyí sì ni ìdí tí ó fi ṣọ̀tẹ̀ sí ọba: Solomoni kọ́ Millo, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dafidi baba rẹ̀. 28Jeroboamu jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Solomoni sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Josẹfu. 29Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jeroboamu ń jáde kúrò ní Jerusalẹmu. Wòlíì Ahijah ti Ṣilo sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá tuntun. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko, 30Ahijah sì gbá agbádá tuntun tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.