Native Bible

1 Kings 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dafidi fi pa ogun Soba run; wọ́n sì lọ sí Damasku, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jẹ ọba ní Damasku.

1 Kings 11:24 in English

1 Kings 11:24 · Berean Standard Bible

and had gathered men to himself. When David killed the Zobaites, Rezon captained a band of raiders and went to Damascus, where they settled and gained control.

Context

22Farao sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?” Hadadi sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!” 23Ọlọ́run sì gbé ọ̀tá mìíràn dìde sí Solomoni, Resoni ọmọ Eliada, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri olúwa rẹ̀, ọba Soba. 24Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dafidi fi pa ogun Soba run; wọ́n sì lọ sí Damasku, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jẹ ọba ní Damasku. 25Resoni sì jẹ́ ọ̀tá Israẹli ní gbogbo ọjọ́ Solomoni, ó ń pa kún ibi ti Hadadi ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Resoni jẹ ọba ní Siria, ó sì ṣòdì sí Israẹli. 26Bákan náà Jeroboamu ọmọ Nebati sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Solomoni, ará Efraimu ti Sereda, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Serua.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.