1 Ọba 11:20
1 Kings 11:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Arábìnrin Tapenesi bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Genubati, ẹni tí Tapenesi tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Genubati ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Farao fúnra rẹ̀.
1 Kings 11:20 in English
1 Kings 11:20 · Berean Standard Bible
And the sister of Tahpenes bore Hadad a son named Genubath. Tahpenes herself weaned him in Pharaoh’s palace, and Genubath lived there among the sons of Pharaoh.
Context
18Wọ́n sì dìde kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Parani wá, wọ́n sì lọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Farao ọba Ejibiti ẹni tí ó fún Hadadi ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ. 19Inú Farao sì dùn sí Hadadi púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tapenesi, ayaba. 20Arábìnrin Tapenesi bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Genubati, ẹni tí Tapenesi tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Genubati ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Farao fúnra rẹ̀. 21Nígbà tí ó sì wà ní Ejibiti, Hadadi sì gbọ́ pé Dafidi ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Joabu olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hadadi wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.” 22Farao sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”
Hadadi sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.