1 Ọba 11:10
1 Kings 11:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Solomoni kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Solomoni kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.
1 Kings 11:10 in English
1 Kings 11:10 · Berean Standard Bible
Although He had warned Solomon explicitly not to follow other gods, Solomon did not keep the LORD’s command.
Context
8Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn. 9Olúwa bínú sí Solomoni nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì. 10Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Solomoni kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Solomoni kò pa àṣẹ Olúwa mọ́. 11Nítorí náà Olúwa wí fún Solomoni pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pàṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmíràn. 12Ṣùgbọ́n, nítorí Dafidi baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.