Native Bible

1 Kings 10:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ohun èlò mímu Solomoni ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lebanoni sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.

1 Kings 10:21 in English

1 Kings 10:21 · Berean Standard Bible

All King Solomon’s drinking cups were gold, and all the utensils of the House of the Forest of Lebanon were pure gold. There was no silver, because it was accounted as nothing in the days of Solomon.

Context

19Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni ìrọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 20Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí. 21Gbogbo ohun èlò mímu Solomoni ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lebanoni sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. 22Ọba sì ní ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hiramu ní Òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tarṣiṣi ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá. 23Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.