Native Bible

1 Kings 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ eyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó.

1 Kings 10:18 in English

1 Kings 10:18 · Berean Standard Bible

Additionally, the king made a great throne of ivory and overlaid it with pure gold.

Context

16Solomoni ọba sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan. 17Ó sì túnṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) asà wúrà lílù, pẹ̀lú òsùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí asà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lebanoni. 18Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ eyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó. 19Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni ìrọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. 20Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.