Native Bible

1 John 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.

1 John 5:6 in English

1 John 5:6 · Berean Standard Bible

This is the One who came by water and blood, Jesus Christ—not by water alone, but by water and blood. And it is the Spirit who testifies to this, because the Spirit is the truth.

Context

4nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. 5Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́? 6Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí. 7Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí. 8Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.