1 Johanu 4:8
1 John 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.
1 John 4:8 in English
1 John 4:8 · Berean Standard Bible
Whoever does not love does not know God, because God is love.
Context
6Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké. 7Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run. 8Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run. 9Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀. 10Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.