1 Johanu 3:17
1 John 3:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?
1 John 3:17 in English
1 John 3:17 · Berean Standard Bible
If anyone with earthly possessions sees his brother in need, but withholds his compassion from him, how can the love of God abide in him?
Context
15Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni, ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀. 16Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 18Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́. 19Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.