Native Bible

1 John 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.

1 John 2:11 in English

1 John 2:11 · Berean Standard Bible

But whoever hates his brother is in the darkness and walks in the darkness. He does not know where he is going, because the darkness has blinded his eyes.

Context

9Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn. 10Ẹni tí ó ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì ṣí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú. 12Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀. 13Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.