Native Bible

1 Corinthians 9:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà.

1 Corinthians 9:26 in English

1 Corinthians 9:26 · Berean Standard Bible

Therefore I do not run aimlessly; I do not fight like I am beating the air.

Context

24Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. 25Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. 26Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. 27Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.