Native Bible

1 Corinthians 7:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,

1 Corinthians 7:33 in English

1 Corinthians 7:33 · Berean Standard Bible

But the married man is concerned about the affairs of this world, how he can please his wife,

Context

31àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ. 32Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.