1 Kọrinti 7:30
1 Corinthians 7:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí,
1 Corinthians 7:30 in English
1 Corinthians 7:30 · Berean Standard Bible
those who weep, as if they did not; those who are joyful, as if they were not; those who make a purchase, as if they had nothing;
Context
28Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́ṣẹ̀, bí a bá gbé wúńdíá ní ìyàwó òun kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ dá a yín sí. 29Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsin yìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí; 30àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí, 31àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí ìgbà ayé yìí ń kọjá lọ. 32Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.