1 Kọrinti 6:16
1 Corinthians 6:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.”
1 Corinthians 6:16 in English
1 Corinthians 6:16 · Berean Standard Bible
Or don’t you know that he who unites himself with a prostitute is one with her in body? For it is said, “The two will become one flesh.”*
Context
14Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. 15Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kristi fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kristi kí ń fi ṣe ẹ̀yà ara àgbèrè bí? Kí a má rí i! 16Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” 17Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dàpọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 18Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè ń ṣe sí ara òun tìkára rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.