1 Kọrinti 5:8
1 Corinthians 5:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.
1 Corinthians 5:8 in English
1 Corinthians 5:8 · Berean Standard Bible
Therefore let us keep the feast, not with the old bread, leavened with malice and wickedness, but with the unleavened bread of sincerity and of truth.
Context
6Ìṣeféfé yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú? 7Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. 8Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo. 9Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. 10Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.