Native Bible

1 Corinthians 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ń ṣe ìgbéraga! Ẹ̀yin kò kúkú káàánú kí a lè mú ẹni tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrín yín?

1 Corinthians 5:2 in English

1 Corinthians 5:2 · Berean Standard Bible

And you are proud! Shouldn’t you rather have been stricken with grief and have removed from your fellowship the man who did this?

Context

1Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà àgbèrè wa láàrín yín, irú àgbèrè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀. 2Ẹ̀yin ń ṣe ìgbéraga! Ẹ̀yin kò kúkú káàánú kí a lè mú ẹni tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrín yín? 3Lóòtítọ́ èmi kò sí láàrín yín nípa ti ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jesu Kristi, mo tí ṣe ìdájọ́ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrín yín. 4Ní orúkọ Jesu Kristi. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi si wa pẹ̀lú yin nínú ẹ̀mí mi àti pẹ̀lú agbára Jesu Kristi Olúwa wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.