1 Kọrinti 5:11
1 Corinthians 5:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
1 Corinthians 5:11 in English
1 Corinthians 5:11 · Berean Standard Bible
But now I am writing you not to associate with anyone who claims to be a brother but is sexually immoral or greedy, an idolater or a verbal abuser, a drunkard or a swindler. With such a man do not even eat.
Context
9Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ènìyàn. 10Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn. 11Ṣùgbọ́n nísinsin yìí mo kọ̀wé sí i yín pé, bí ẹnikẹ́ni tí a pe rẹ̀ ni arákùnrin bá jẹ́ àgbèrè, tàbí wọ̀bìà, tàbí abọ̀rìṣà, àti ẹlẹ́gàn, tàbí ọ̀mùtípara, tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí ẹ tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. 12Nítorí èwo ni tèmi láti máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń bẹ lóde? Kì í ha ṣe àwọn tí ó wà nínú ni ẹ̀yin ṣe ìdájọ́ wọn? 13Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó ń bẹ lóde. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrín yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.