Native Bible

1 Corinthians 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

1 Corinthians 16:11 in English

1 Corinthians 16:11 · Berean Standard Bible

No one, then, should treat him with contempt. Send him on his way in peace so that he can return to me, for I am expecting him along with the brothers.

Context

9Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ. 10Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù, nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. 11Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin. 12Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un. 13Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.