1 Kọrinti 15:53
1 Corinthians 15:53 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀.
1 Corinthians 15:53 in English
1 Corinthians 15:53 · Berean Standard Bible
For the perishable must be clothed * with the imperishable, and the mortal with immortality.
Context
51Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín, gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà. 52Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà. 53Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. 54Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.” 55“Ikú, oró rẹ dà?
Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.