1 Kọrinti 14:9
1 Corinthians 14:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán.
1 Corinthians 14:9 in English
1 Corinthians 14:9 · Berean Standard Bible
So it is with you. Unless you speak intelligible words with your tongue, how will anyone know what you are saying? You will just be speaking into the air.
Context
7Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí? 8Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun? 9Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán. 10Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀. 11Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ ìtumọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó jásí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí jásí aláìgbédè sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.