Native Bible

1 Corinthians 14:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá?

1 Corinthians 14:36 in English

1 Corinthians 14:36 · Berean Standard Bible

Did the word of God originate with you? Or are you the only ones it has reached?

Context

34Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ìjọ, nítorí a kò fi fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn wà lábẹ́ ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin pẹ̀lú ti wí. 35Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. 36Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá? 37Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tàbí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé òfin Olúwa ni wọ́n. 38Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá fi ojú fo èyí dá, òun fúnra rẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.