1 Kọrinti 14:17
1 Corinthians 14:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítòótọ́, ṣùgbọ́n a kó fi ẹsẹ̀ ẹnìkejì rẹ múlẹ̀.
1 Corinthians 14:17 in English
1 Corinthians 14:17 · Berean Standard Bible
You may be giving thanks well enough, but the other one is not edified.
Context
15Ǹjẹ́ kín ni èmi yóò ṣe? Èmi yóò fi ẹ̀mí mi gbàdúrà, èmi yóò sí fi òye mi gbàdúrà pẹ̀lú; Èmi yóò fi ẹ̀mí mi kọrin, èmi yóò sí fi òye mi kọrin pẹ̀lú. 16Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá yin Ọlọ́run nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ wí? 17Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítòótọ́, ṣùgbọ́n a kó fi ẹsẹ̀ ẹnìkejì rẹ múlẹ̀. 18Mó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí èmi ń fọ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ. 19Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fi ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.