1 Kọrinti 11:25
1 Corinthians 11:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”
1 Corinthians 11:25 in English
1 Corinthians 11:25 · Berean Standard Bible
In the same way, after supper He took the cup, saying, “This cup is the new covenant in My blood; do this, as often as you drink it, in remembrance of Me.”
Context
23Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. 24Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” 25Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” 26Nítorí nígbàkígbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé. 27Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.