1 Kọrinti 10:29
1 Corinthians 10:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn.
1 Corinthians 10:29 in English
1 Corinthians 10:29 · Berean Standard Bible
the other one’s conscience, I mean, not your own. For why should my freedom be determined by someone else’s conscience?
Context
27Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn. 28Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn. 29Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn. 30Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún. 31Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.