1 Kronika 9:29
1 Chronicles 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn.
1 Chronicles 9:29 in English
1 Chronicles 9:29 · Berean Standard Bible
Others were put in charge of the furnishings and other articles of the sanctuary, as well as the fine flour, wine, oil, frankincense, and spices.
Context
27Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀. 28Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. 29Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. 30Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. 31Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.