1 Kronika 4:12
1 Chronicles 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.
1 Chronicles 4:12 in English
1 Chronicles 4:12 · Berean Standard Bible
Eshton was the father of Beth-rapha, of Paseah, and of Tehinnah the father of Ir-nahash. These were the men of Recah.
Context
10Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún mi, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀. 11Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka. 13Àwọn ọmọ Kenasi:
Otnieli àti Seraiah.
Àwọn ọmọ Otnieli:
Hatati àti Meonotai. 14Meonotai sì ni baba Ofira.
Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,
baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.