1 Kronika 29:27
1 Chronicles 29:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu.
1 Chronicles 29:27 in English
1 Chronicles 29:27 · Berean Standard Bible
The length of David’s reign over Israel was forty years—seven years in Hebron and thirty-three years in Jerusalem.
Context
25Olúwa gbé Solomoni ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Israẹli, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọláńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú rẹ̀ tí ó jẹ lórí Israẹli. 26Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. 27Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 28Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 29Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dafidi, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Samuẹli aríran, ìwé ìrántí ti Natani wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gadi aríran,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.