1 Kronika 28:3
1 Chronicles 28:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀.’
1 Chronicles 28:3 in English
1 Chronicles 28:3 · Berean Standard Bible
but God said to me, ‘You are not to build a house for My Name, because you are a man of war who has spilled blood.’
Context
1Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu. Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀. 2Ọba Dafidi dìde dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀, o sì wí pé, “Fetísílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni lọ́kàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ. 3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀.’ 4“Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Israẹli, títí láé. Ó yan Juda gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Juda, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Israẹli. 5Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Solomoni láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lórí Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.