Native Bible

1 Chronicles 27:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.

1 Chronicles 27:3 in English

1 Chronicles 27:3 · Berean Standard Bible

He was a descendant of Perez and chief of all the army commanders for the first month.

Context

1Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin. 2Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. 3Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní. 4Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. 5Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.