1 Kronika 22:3
1 Chronicles 22:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n.
1 Chronicles 22:3 in English
1 Chronicles 22:3 · Berean Standard Bible
David provided a large quantity of iron to make the nails for the doors of the gateways and for the fittings, together with more bronze than could be weighed
Context
1Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.” 2Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. 3Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. 4Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi. 5Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.