1 Kronika 20:4
1 Chronicles 20:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri pẹ̀lú àwọn ará Filistini, ní àkókò yìí ni Sibekai ará Huṣati pa Sipai, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Refaimu, àti àwọn ará Filistini ni a ṣẹ́gun.
1 Chronicles 20:4 in English
1 Chronicles 20:4 · Berean Standard Bible
Some time later, war broke out with the Philistines at Gezer. At that time Sibbecai the Hushathite killed Sippai,* a descendant of the Rephaim,* and the Philistines were subdued.
Context
2Dafidi mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n rẹ̀ dàbí i tálẹ́ǹtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye. A sì gbé e ka orí Dafidi. Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà. 3Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dafidi ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ammoni. Nígbà náà, Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu. 4Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri pẹ̀lú àwọn ará Filistini, ní àkókò yìí ni Sibekai ará Huṣati pa Sipai, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Refaimu, àti àwọn ará Filistini ni a ṣẹ́gun. 5Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Filistini, Elhanani ọmọ Jairi pa Lahmi arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunṣọ. 6Síbẹ̀síbẹ̀ nínú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gati, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Rafa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.