Native Bible

1 Chronicles 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú.

1 Chronicles 19:18 in English

1 Chronicles 19:18 · Berean Standard Bible

But the Arameans fled before Israel, and David killed seven thousand of their charioteers and forty thousand foot soldiers. He also killed Shophach the commander of their army.

Context

16Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Siria rí wí pé àwọn Israẹli ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Siria rékọjá odò Eufurate wá, pẹ̀lú Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun Hadadeseri, tí ó ń darí wọn. 17Nígbà tí a sọ fún Dafidi nípa èyí, ó pe gbogbo Israẹli jọ wọ́n sì rékọjá Jordani; Ó lọ síwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dafidi fa ìlà rẹ̀ láti bá àwọn ará Siria jagun wọ́n sì dojú ìjà kọ ọ́. 18Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú. 19Nígbà tí àwọn ẹrú Hadadeseri rí i wí pé Israẹli ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dafidi, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Siria kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ammoni lọ́wọ́ mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.