Native Bible

1 Chronicles 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

1 Chronicles 18:6 in English

1 Chronicles 18:6 · Berean Standard Bible

Then he placed garrisons * in Aram of Damascus, and the Arameans became subject to David and brought him tribute. So the LORD made David victorious * wherever he went.

Context

4Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà. 5Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) wọn bọ lẹ̀. 6Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ. 7Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. 8Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.